Igboho-more, omo alagbado ode
Omo atapete inu omi
Omo gegele l’odo Sanya
Iwosi ni won ko, omo alagbado ode.
Alejo to ba fe fiwosi lo won, ni Igboho nko iwosi fun,
B’alejo ba mule nihin, Igboho a ni ile baba awon ni
B’oo mule lohun, Igboho a n’ile baba awon ni
Ile gbogbo kiki okun.
Awon inaki iwoyi ni won n seke
Won l’awon ko ni b’omi Konsin mu
Sugbon won sun kerekere
Won bu omi Konsin s’enu
Won si n bu odo Sanya fo’se
Omi odo Sanya o de mi larin idi,
Omi Konsin n se si mi l’enu
Omo esin ko bi meji ni Igboho
Esin i ba bi m’eji, ao ba f’okan bo Osanta,
Ki a fi ekeji bo Sanya
A o ba mu’ya esin se eru,
Eru godogbo sanwo esin
Omo mo l’oke kan ti n ba won je Abenugboro
Omo oke ti won o gbodo gun
Omo okuta meta Igboho,
Okan n se mi ni maa rora, ma rora
Ekeji n se mi ni pele pele
Eketa ni nigba t’oo m’ona
Ki lo ba won wa de ‘Gboho m’ore si
Omo alagbado ode
Omo abere meta ode aye
Okan se, ikeji te,
Iketa to ku ni gbogbo omo araye fi n ranso
E ku o, Omo Alagbado ode
Omo atapete inu omi.
Leave A Comment